IWUN TÚTÚ

L'ɛ́kpasɛ̀ Ìyìn rere ɔ́ tútú si lí èdè Ìdàáshà ɔ́, àa ɛ́ɛ yɔ́ɔ wí ní àá ti she kpíkpɔ̀ lá ɛ̀. Lí èyítɔ́ ɔ́, àá ti tú méjìdílógú (18) líìtá méjelélógójì (27) yèé àa ɛ kó she àan ɔ́; báni ó bɔ mɛsán (09) shí àa kó mú já l'ágbóra Ɔlɔ́run.

Yèé àá ti tú, shí à ti shagbɛ́yɛ̀wò an ɔ́ nìí: - Ìyìn rere ti Matiéè - Ìyìn rere ti Màákì - Ìyìn rere ti Lùúkì - Ìyìn rere ti Jàán - Ìwé ìshe jɛunkún an - Ìwé àkpàshɛ̀ fí ɔni Korɛ́ntì an - Ìwé èkéjì fí ɔni Korɛ́ntìn an - Ìwé fí ɔni Efɛ́sì an - Ìwé fí ɔni Filípù an - Ìwé fí ɔni Kolósì an - Ìwé àkpàshɛ̀ fí ɔni Tɛsaloníkì an - Ìwé èkéjì fí ɔni Tɛsaloníkì an - Ìwé-e Timotéè àkpàshɛ̀ - Ìwé-e Timotéè èkéjì - Ìwé-e Títì - Ìwé-e Filemɔ́ɔ̀ - Ìwé Ébérù an - Ìwé-e Jùúdì